Welcome to PraiseZion

HOME |   |  DOWNLOAD APP |  OPPORTUNITIES |  SERMONS
|  JOBS |  INSTRUMENTAL | MIXTAPES |  DEVOTIONAL

SEARCH CONTENTS (Use Name Or Title)

Shola Allyson – Isin

Isin by Shola Allyson Mp3 Download + Lyrics 

Download this track from Shola Allyson titled Isin. Sola Allyson-Obaniyi, popularly known as Shola Allyson or Sola Allyson, is a Nigerian soul, folk, and gospel singer and songwriter.

Use this link below to stream and download the track

Lyrics Of Isin by Shola Allyson

A f’ope f’OlorunL’okan ati l’ohun waEni s’ohun ‘yanuN’nu Eni t’araye n yoGbat’a wa l’om’owoOn na l’o ntoju waO si f’ebun ifeSe ‘toju wa sibe
Oba OnibuoreMa fi wa sile laelaeAyo ti ko l’opinOn ‘bukun y’o je ti waPa wa mo ninu ooreTo wa, gb’a ba damuYo wa ninu ibiL’aye ati l’orun
K’a f’iyin on opeF’Olorun, Baba, OmoAti Emi mimoTi o ga julo lorunOlorun kan laelaeT’aye at’orun n boBee lo wa di isiyiBeeni yo wa laelae
Eyo ninu Oluwa, e yoEyin t’okan re se dedeEyin t’o ti yan OluwaLe ‘banuje at’aro lo
E yo! E yo!E yo ninu Oluwa, e yo!E yo! E yo!E yo ninu Oluwa, e yo!
E yo tor’ On l’OluwaL’aye ati l’orun peluOro Re bor’ ohun gbogboO l’agbara lati gbala
E yo! E yo!E yo ninu Oluwa, e yo!E yo! E yoE yo ninu Oluwa, e yo!
‘Gbat’ a ba n ja ija rereTi ota fere bori waOgun Olorun t’a ko riPo ju awon ota wa lo
E yo! E yo!E yo ninu Oluwa, e yo!E yo! E yoE yo ninu Oluwa, e yo!
Okan mi n yo ninu Oluwa‘Tori O je iye fun miOhun Re dun pupo lati gboAdun ni lati r’oju Re
Emi n yo ninu ReEmi n yo ninu ReGba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi‘Tori emi n yo ninu Re
O ti n wa mi pe ki n to mo O‘Gbati mo rin jina s’agboO gbe mi wa sile l’apa ReNibi ti papa tutu wa
Emi n yo ninu ReEmi n yo ninu ReGba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi‘Tori emi nyo ninu Re
Oore at’anu Re yi mi kaOr’ofe Re n san bi odoEmi Re n to, o si n se ‘tunuO mba mi lo si ‘bikibi
Emi n yo ninu ReEmi n yo ninu ReGba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi‘Tori emi nyo ninu Re
Iwo to fe wa la o ma sin titiOluwa Oloore waIwo to nso wa ninu ‘danwo ayeMimo logo Ola Re
Baba, Iwo l’a o ma sinBaba, Iwo l’a o ma boIwo to fe wa l’a o ma sin titiMimo l’ogo ola Re
Iwo to f’agan l’omo to n pe ranseNinu ola Re to gaEni t’o ti s’alaileso si n dupeFun ‘se ogo ola Re
Baba, Iwo l’a o ma sinBaba, Iwo l’a o ma boIwo to fe wa l’a o ma sin titiMimo l’ogo ola Re
Eni t’ebi n pa le ri ayo ninuAgbara nla Re to ga oAwon to ti n woju Re fun aanuWon tun n yo ninu ise Re
Baba, Iwo l’a o ma sinBaba, Iwo l’a o ma boIwo to fe wa l’a o ma sin titiMimo l’ogo ola Re
Baba E se aanu Yin duroBaba E se oBaba E se o, aanu Yin duro
Baba E se aanu Yin duroBaba E seBaba E se oBaba E se, aanu Yin duro
Eyin ni o, Olorun oEledumare, Oba ogoEyin ni o, OlorunAwimayehun, Alagbara
Eyin ni o, Olorun oEledumare, Oga ogoEyin ni o, Olorun oAwimayehun, Alagbara
K’a to da aye, n’Iwo ti waK’ole mi to so ninu iya mi, l’O ti n jobaOlorun Baba o, Olorun omoOlorun Emi mimoIwo n’ibere ohun gbogboIwo ni opin ohun gbogboAwimayehun, Alagbara
Eyin ni o, Olorun oEledumare, Oga ogoEyin ni o, Olorun oAwimayehun, Alagbara
Oluwa orun on aye‘Wo n’iyin at’ope ye funBawo la ba ti fe O to!Onibu ore
Orun ti n ran, at’ afefeGbogbo eweko n so ‘fe Re‘Wo l’O n mu irugbin daraOnibu ore
Onibu oreBawo la ba ti fe O to!Onibu ore
Fun ara lile wa gbogboFun gbogbo ibukun ayeAwa yin O, a si dupeOnibu ore
Fun idariji ese waAti fun ireti orunKi l’ohun t’a ba fifun OOnibu ore
Onibu oreBawo la ba ti fe O to!Onibu ore
O se mi laanu, ma a polongo ReOba t’o se mi laanu, eh eh, ah ahMa a polongo Re
O se mi laanu, ma a polongo ReOba t’o se mi laanu, eh eh, ah ahMa a polongo Re
Oju mi ti ri, eti mi ti gboEnu mi ma soro n’pa ise OluwaOju mi ti ri o, eti mi ti gboEnu mi ma soro n’pa ise Oluwa
Oju mi ti ri, eti mi ti gboEnu mi ma soro n’pa ise OluwaOju mi ti ri, eti mi ti gboEnu mi ma soro n’pa ise Oluwa
Olori ijo t’orunL’ayo l’a wole fun OK’O to de, ijo t’ayeY’o ma korin bi t’orunA gbe okan wa s’okeNi ‘reti t’o ni ‘bukunAwa kigbe, awa f’iyinF’Olorun igbala wa
Bi a wa ninu ‘ponjuT’a n koja ninu inaOrin ife l’awa yo koTi yo mu wa sun mo OAwa n sape, a si yoNinu ojurere ReIfe t’o so wa di TireY’o pa wa mo titi lae
Iwo mu awon eeyan ReKoja isan idanwoA k’ yo beru wahalaTori O wa nitosiAye, ese, at’EsuKoju ‘ja si wa lasanL’agbara Re, a o segunA o si ko orin Mose
Aribiti, ArabataEyin l’atobijuAribiti, ArabataEyin l’atobijuOluwa
Oluwa, Eyin l’atobijuAribiti, ArabataEyin l’atobijuAribiti, ArabataEyin l’atobijuOluwa
Lat’ojo ti mo ti n rinEh oh, eh eh eh eh ohEmi o ri ‘ru Olorun eyi riEh oh, eh oh
Lat’ojo ti mo ti n rinEh oh, eh ohEmi o ri ‘ru Olorun eyi riEh oh, eh oh
Ojo nla l’ojo ti mo yanOlugbala l’Olorun miO ye ki okan mi ma yoK’o si ro ihin na kale
Ojo nla l’ojo naTi Jesu we ese mi nuO ko mi ki n ma gbaduraKi n ma sora, ki n si ma yoOjo nla l’ojo naTi Jesu we ese mi nu
Ise igbala pari naEmi di t’Oluwa mi loni ati lojo gbogboOhun l’o pe mi, ti mo si je oMo f’ayo j’ipe mimo na
Ojo nla l’ojo naTi Jesu we ese mi nuO ko mi ki n ma gbaduraKi n ma sora, ki n si ma yoOjo nla l’ojo naTi Jesu we ese mi nu
Eyin orun gbo eje mi,Eje mi ni ojojumoEmi y’o ma so dotun titiIku yo fi mu mi rele
Ojo nla l’ojo naTi Jesu we ese mi nuO ko mi ki n ma gbaduraKi n ma sora, ki n si ma yoOjo nla l’ojo naTi Jesu we ese mi nu
Gbese ope mi po, emi o le san tanAmo o sibesibe, ma a se ‘won ti mo le seBaba Alaanu mi, E ma se o Baba
Gbese ope mi po, emi o le san tanAmo o sibesibe, ma a se ‘won ti mo le seBaba Alaanu mi, E ma se o Baba
Mo n tesiwaju l’ona naMo n goke sii lojojumoMo n gbadura bi mo ti n loOluwa jo gbe mi soke
Oluwa, jo gbe mi sokeFa mi lo si ibi gigaApata t’o ga ju mi loOluwa jo gbe mi soke
Ife okan mi ko duroLaarin ‘yemeji at’eruAwon miran le ma gbe beIbi giga l’okan mi n fe
Oluwa, jo gbe mi sokeFa mi lo si ibi gigaApata t’o ga ju mi loOluwa jo gbe mi soke
Mo fe de ‘bi giga juloNinu ogo didan juloMo n gbadura ki n le de beOluwa mu mi de ‘le na
Oluwa, jo gbe mi sokeFa mi lo si ibi gigaApata t’o ga ju mi loOluwa jo gbe mi soke
Igbagbo mi duro l’oriEje at’ ododo JesuN ko je gbekele ohun kanLeyin oruko nla Jesu
Mo duro le Kristi ApataIle miran, iyanrin niMo duro le Kristi ApataIle miran, iyanrin ni
B’ire-ije mi tile gunOre-ofe Re ko yi padaB’o ti wu ki iji na le toIdakoro mi ko niye
Mo duro le Kristi ApataIle miran, iyanrin niMo duro le Kristi ApataIle miran, iyanrin ni
Ore-ofe, ohunAdun ni l’eti waGbohun-gbohun re y’o gba orun kanAye y’o gbo pelu
Ore-Ofe saN’igbekele miJesu ku fun arayeO ku fun mi pelu
Ore-Ofe to miS’ona alaafiaO n toju mi l’ojojumoNi irin ajo mi
Ore-Ofe saN’igbekele miJesu ku fun arayeO ku fun mi pelu
Je k’ ore-ofe yiF’agbara fokan miKi n le fi gbogbo ipa miAt’ ojo mi fun O
Ore-Ofe saN’igbekele miJesu ku fun arayeO ku fun mi pelu
Ninu irin ajo mi, beeni mo n korinMo n toka si Kalfari, nibi eje naIdanwo lode ninu, l’ota gbe dideJesu l’O nto mi lo, isegun daju
A! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju ReKi n ma korin titi, nipa oore ReNi ilu ogo ni, ki n gbohun sokePe mo bo, ija tan, mo de ile mi
Ninu ise isin mi, b’okunkun ba suUn o tubo sunmo Jesu, y’O tan imoleEsu le gb’ ogun ti mi ki nle sa padaJesu l’o nto mi lo, ko s’ewu fun mi
A! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju ReKi n ma korin titi, nipa oore ReNi ilu ogo ni, ki n gbohun sokePe mo bo, ija tan, mo de ile mi
Bi mo tile bo sinu afonifojiImole itoni Re y’o mole si miY’o na owo Re si mi, y’O gbe mi sokeUn o tesiwaju b’O ti n to mi lo
Nigbati iji aye yi ba yi lu miMo ni abo t’o daju labe apa ReY’O ma f’owo Re to mi titi de opinOre ododo ni, A! mo ti f’E to
A! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju ReKi n ma korin titi, nipa oore ReNi ilu ogo ni ki n gbohun sokePe mo bo, ija tan, mo de ile mi
Nipa ife OlugbalaKi y’o si nkanOju rere Re ki padaKi y’o si nkanOwon l’eje t’o wo wa sanPipe l’edidi or’ofeAgbara l’owo t’o n gba niKo le si nkan
Bi a wa ninu iponjuKi y’o si nkanIgbala kikun ni tiwaKi y’o si nkanIgbekele Olorun dunGbigbe ninu Kristi l’ereEmi si n so wa di mimoKo le si nkan
Ojo ola yio daraKi y’o si nkan‘Gbagbo le korin ni ‘ponjuKi y’o si nkanA gbekele ‘fe Baba waJesu n fun wa l’ohun gbogboNi yiye tabi ni kikuKo le si nkanAmin.
 
Download Mp3 Here

| Categories: Music

CLICK HERE TO COMMENT ON THIS POST

WE ARE ON SOCIAL MEDIA

Facebook | Twitter | Instagram | Youtube

0 Comments

LEAVE A COMMENT

Type Name Below

Type Comment Below

« | »