Shola Allyson – Isin
Isin by Shola Allyson Mp3 Download + Lyrics
Download this track from Shola Allyson titled Isin. Sola Allyson-Obaniyi, popularly known as Shola Allyson or Sola Allyson, is a Nigerian soul, folk, and gospel singer and songwriter.
Use this link below to stream and download the track
Lyrics Of Isin by Shola Allyson
A f’ope f’Olorun
L’okan ati l’ohun wa Eni s’ohun ‘yanu N’nu Eni t’araye n yo Gbat’a wa l’om’owo On na l’o ntoju wa O si f’ebun ife Se ‘toju wa sibeOba Onibuore
Ma fi wa sile laelae Ayo ti ko l’opin On ‘bukun y’o je ti wa Pa wa mo ninu oore To wa, gb’a ba damu Yo wa ninu ibi L’aye ati l’orunK’a f’iyin on ope
F’Olorun, Baba, Omo Ati Emi mimo Ti o ga julo lorun Olorun kan laelae T’aye at’orun n bo Bee lo wa di isiyi Beeni yo wa laelaeEyo ninu Oluwa, e yo
Eyin t’okan re se dede Eyin t’o ti yan Oluwa Le ‘banuje at’aro loE yo! E yo!
E yo ninu Oluwa, e yo! E yo! E yo! E yo ninu Oluwa, e yo!E yo tor’ On l’Oluwa
L’aye ati l’orun pelu Oro Re bor’ ohun gbogbo O l’agbara lati gbalaE yo! E yo!
E yo ninu Oluwa, e yo! E yo! E yo E yo ninu Oluwa, e yo!‘Gbat’ a ba n ja ija rere
Ti ota fere bori wa Ogun Olorun t’a ko ri Po ju awon ota wa loE yo! E yo!
E yo ninu Oluwa, e yo! E yo! E yo E yo ninu Oluwa, e yo!Okan mi n yo ninu Oluwa
‘Tori O je iye fun mi Ohun Re dun pupo lati gbo Adun ni lati r’oju ReEmi n yo ninu Re
Emi n yo ninu Re Gba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi ‘Tori emi n yo ninu ReO ti n wa mi pe ki n to mo O
‘Gbati mo rin jina s’agbo O gbe mi wa sile l’apa Re Nibi ti papa tutu waEmi n yo ninu Re
Emi n yo ninu Re Gba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi ‘Tori emi nyo ninu ReOore at’anu Re yi mi ka
Or’ofe Re n san bi odo Emi Re n to, o si n se ‘tunu O mba mi lo si ‘bikibiEmi n yo ninu Re
Emi n yo ninu Re Gba gbogbo lo n fi ayo kun okan mi ‘Tori emi nyo ninu ReIwo to fe wa la o ma sin titi
Oluwa Oloore wa Iwo to nso wa ninu ‘danwo aye Mimo logo Ola ReBaba, Iwo l’a o ma sin
Baba, Iwo l’a o ma bo Iwo to fe wa l’a o ma sin titi Mimo l’ogo ola ReIwo to f’agan l’omo to n pe ranse
Ninu ola Re to ga Eni t’o ti s’alaileso si n dupe Fun ‘se ogo ola ReBaba, Iwo l’a o ma sin
Baba, Iwo l’a o ma bo Iwo to fe wa l’a o ma sin titi Mimo l’ogo ola ReEni t’ebi n pa le ri ayo ninu
Agbara nla Re to ga o Awon to ti n woju Re fun aanu Won tun n yo ninu ise ReBaba, Iwo l’a o ma sin
Baba, Iwo l’a o ma bo Iwo to fe wa l’a o ma sin titi Mimo l’ogo ola ReBaba E se aanu Yin duro
Baba E se o Baba E se o, aanu Yin duroBaba E se aanu Yin duro
Baba E se Baba E se o Baba E se, aanu Yin duroEyin ni o, Olorun o
Eledumare, Oba ogo Eyin ni o, Olorun Awimayehun, AlagbaraEyin ni o, Olorun o
Eledumare, Oga ogo Eyin ni o, Olorun o Awimayehun, AlagbaraK’a to da aye, n’Iwo ti wa
K’ole mi to so ninu iya mi, l’O ti n joba Olorun Baba o, Olorun omo Olorun Emi mimo Iwo n’ibere ohun gbogbo Iwo ni opin ohun gbogbo Awimayehun, AlagbaraEyin ni o, Olorun o
Eledumare, Oga ogo Eyin ni o, Olorun o Awimayehun, AlagbaraOluwa orun on aye
‘Wo n’iyin at’ope ye fun Bawo la ba ti fe O to! Onibu oreOrun ti n ran, at’ afefe
Gbogbo eweko n so ‘fe Re ‘Wo l’O n mu irugbin dara Onibu oreOnibu ore
Bawo la ba ti fe O to! Onibu oreFun ara lile wa gbogbo
Fun gbogbo ibukun aye Awa yin O, a si dupe Onibu oreFun idariji ese wa
Ati fun ireti orun Ki l’ohun t’a ba fifun O Onibu oreOnibu ore
Bawo la ba ti fe O to! Onibu oreO se mi laanu, ma a polongo Re
Oba t’o se mi laanu, eh eh, ah ah Ma a polongo ReO se mi laanu, ma a polongo Re
Oba t’o se mi laanu, eh eh, ah ah Ma a polongo ReOju mi ti ri, eti mi ti gbo
Enu mi ma soro n’pa ise Oluwa Oju mi ti ri o, eti mi ti gbo Enu mi ma soro n’pa ise OluwaOju mi ti ri, eti mi ti gbo
Enu mi ma soro n’pa ise Oluwa Oju mi ti ri, eti mi ti gbo Enu mi ma soro n’pa ise OluwaOlori ijo t’orun
L’ayo l’a wole fun O K’O to de, ijo t’aye Y’o ma korin bi t’orun A gbe okan wa s’oke Ni ‘reti t’o ni ‘bukun Awa kigbe, awa f’iyin F’Olorun igbala waBi a wa ninu ‘ponju
T’a n koja ninu ina Orin ife l’awa yo ko Ti yo mu wa sun mo O Awa n sape, a si yo Ninu ojurere Re Ife t’o so wa di Tire Y’o pa wa mo titi laeIwo mu awon eeyan Re
Koja isan idanwo A k’ yo beru wahala Tori O wa nitosi Aye, ese, at’Esu Koju ‘ja si wa lasan L’agbara Re, a o segun A o si ko orin MoseAribiti, Arabata
Eyin l’atobiju Aribiti, Arabata Eyin l’atobiju OluwaOluwa, Eyin l’atobiju
Aribiti, Arabata Eyin l’atobiju Aribiti, Arabata Eyin l’atobiju OluwaLat’ojo ti mo ti n rin
Eh oh, eh eh eh eh oh Emi o ri ‘ru Olorun eyi ri Eh oh, eh ohLat’ojo ti mo ti n rin
Eh oh, eh oh Emi o ri ‘ru Olorun eyi ri Eh oh, eh ohOjo nla l’ojo ti mo yan
Olugbala l’Olorun mi O ye ki okan mi ma yo K’o si ro ihin na kaleOjo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu O ko mi ki n ma gbadura Ki n ma sora, ki n si ma yo Ojo nla l’ojo na Ti Jesu we ese mi nuIse igbala pari na
Emi di t’Oluwa mi loni ati lojo gbogbo Ohun l’o pe mi, ti mo si je o Mo f’ayo j’ipe mimo naOjo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu O ko mi ki n ma gbadura Ki n ma sora, ki n si ma yo Ojo nla l’ojo na Ti Jesu we ese mi nuEyin orun gbo eje mi,
Eje mi ni ojojumo Emi y’o ma so dotun titi Iku yo fi mu mi releOjo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu O ko mi ki n ma gbadura Ki n ma sora, ki n si ma yo Ojo nla l’ojo na Ti Jesu we ese mi nuGbese ope mi po, emi o le san tan
Amo o sibesibe, ma a se ‘won ti mo le se Baba Alaanu mi, E ma se o BabaGbese ope mi po, emi o le san tan
Amo o sibesibe, ma a se ‘won ti mo le se Baba Alaanu mi, E ma se o BabaMo n tesiwaju l’ona na
Mo n goke sii lojojumo Mo n gbadura bi mo ti n lo Oluwa jo gbe mi sokeOluwa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga Apata t’o ga ju mi lo Oluwa jo gbe mi sokeIfe okan mi ko duro
Laarin ‘yemeji at’eru Awon miran le ma gbe be Ibi giga l’okan mi n feOluwa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga Apata t’o ga ju mi lo Oluwa jo gbe mi sokeMo fe de ‘bi giga julo
Ninu ogo didan julo Mo n gbadura ki n le de be Oluwa mu mi de ‘le naOluwa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga Apata t’o ga ju mi lo Oluwa jo gbe mi sokeIgbagbo mi duro l’ori
Eje at’ ododo Jesu N ko je gbekele ohun kan Leyin oruko nla JesuMo duro le Kristi Apata
Ile miran, iyanrin ni Mo duro le Kristi Apata Ile miran, iyanrin niB’ire-ije mi tile gun
Ore-ofe Re ko yi pada B’o ti wu ki iji na le to Idakoro mi ko niyeMo duro le Kristi Apata
Ile miran, iyanrin ni Mo duro le Kristi Apata Ile miran, iyanrin niOre-ofe, ohun
Adun ni l’eti wa Gbohun-gbohun re y’o gba orun kan Aye y’o gbo peluOre-Ofe sa
N’igbekele mi Jesu ku fun araye O ku fun mi peluOre-Ofe to mi
S’ona alaafia O n toju mi l’ojojumo Ni irin ajo miOre-Ofe sa
N’igbekele mi Jesu ku fun araye O ku fun mi peluJe k’ ore-ofe yi
F’agbara fokan mi Ki n le fi gbogbo ipa mi At’ ojo mi fun OOre-Ofe sa
N’igbekele mi Jesu ku fun araye O ku fun mi peluNinu irin ajo mi, beeni mo n korin
Mo n toka si Kalfari, nibi eje na Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide Jesu l’O nto mi lo, isegun dajuA! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju Re
Ki n ma korin titi, nipa oore Re Ni ilu ogo ni, ki n gbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile miNinu ise isin mi, b’okunkun ba su
Un o tubo sunmo Jesu, y’O tan imole Esu le gb’ ogun ti mi ki nle sa pada Jesu l’o nto mi lo, ko s’ewu fun miA! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju Re
Ki n ma korin titi, nipa oore Re Ni ilu ogo ni, ki n gbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile miBi mo tile bo sinu afonifoji
Imole itoni Re y’o mole si mi Y’o na owo Re si mi, y’O gbe mi soke Un o tesiwaju b’O ti n to mi loNigbati iji aye yi ba yi lu mi
Mo ni abo t’o daju labe apa Re Y’O ma f’owo Re to mi titi de opin Ore ododo ni, A! mo ti f’E toA! mo fe ri Jesu, ki n ma w’ oju Re
Ki n ma korin titi, nipa oore Re Ni ilu ogo ni ki n gbohun soke Pe mo bo, ija tan, mo de ile miNipa ife Olugbala
Ki y’o si nkan Oju rere Re ki pada Ki y’o si nkan Owon l’eje t’o wo wa san Pipe l’edidi or’ofe Agbara l’owo t’o n gba ni Ko le si nkanBi a wa ninu iponju
Ki y’o si nkan Igbala kikun ni tiwa Ki y’o si nkan Igbekele Olorun dun Gbigbe ninu Kristi l’ere Emi si n so wa di mimo Ko le si nkanOjo ola yio dara
Ki y’o si nkan ‘Gbagbo le korin ni ‘ponju Ki y’o si nkan A gbekele ‘fe Baba wa Jesu n fun wa l’ohun gbogbo Ni yiye tabi ni kiku Ko le si nkan Amin.